A nilo owo (bi #30,000) lati ma ba iṣe yii lọ. Ti ẹ ba fẹ polowo ọja yin lori AwaYoruba tabi ẹ fẹ fi owo ran AwaYoruba lọwọ, ẹ kan si wa ni admin@awayoruba.com. E ṣe pupọ.
We need money (about #30,000) to continue this work. If you want to advertise on Awayoruba or you'd like to donate money to help this website, please contact us at admin@awayoruba.com. Thank you.

Tribal marks in Yoruba land and types

E ko awon akole ti ko ba jo mo awon eyi ti a pese aye fun. (Create a topic that does not fall under the forums already created)
Post Reply
sofunbej
Reactions:
Posts: 16
Joined: Thu Nov 10, 2016 11:29 am
Gender: Male

Tribal marks in Yoruba land and types

Post by sofunbej » Tue Jan 31, 2017 10:02 pm

Besides Yoruba language [http://www.businesshealthsupport.com/in ... ishyoruba/] another aspect of Yoruba culture that must be cherished is the tribal marks. Although tribal marks have been cancelled in many families because of civilisation, however it is still retained in some. Both male and female have marks. We shall examine in this piece the reasons for tribal marks, some places or towns that are identified with certain tribal marks, with few examples. This discussion on tribal marks may not be exhaustive, the idea is to rekindle interest in this dwindling aspect of Yoruba culture.

Reasons for tribal marks in Yoruba land

The Yoruba put marks on their children for two main reasons. The first reason is for identification. In the old days, during inter-tribal wars, and slave trade many families lost their children, able-bodied young men, wives and fathers. Those who were not killed were carried to foreign lands. In some cases, some returned. Therefore, inorder for proper identification of their relations on return the idea of tribal marks was introduced. The second reason is for beauty. If you look at the faces of those who have marks you will discover that they are beautiful or handsome. Although it is said that beauty is in the eyes of the beholder, nevertheless it is believed that tribal marks add to one’s beauty.

Some places that have tribal marks
In Yorubaland some people or places are identified with certain tribal marks. These include the Egbas, Ibadan, Ifes, Ijeshas, Oyos, Ekitis, Ijebus, Ondos, and Owus. The tribal marks are of different types namely, Abaja, Pele, Ture, Gombo, and Keke.

=======================
ILA KIKO NI ILE YORUBA

Okan lara asa Yoruba ti a gbodo gbe laruge ni ila kiko. Botileje wipe opolopo idile lo ti pa asa ile kiko ti nitori olaju, sibesibe awon miran si nkola titidi isisiyi. Atokunrin atobirin lo nkola. Ninu atejade yi, a o se agbeyewo idi ti ila kiko fi waye nile Yoruba, ati awon ila to wopo laarin awon ilu sarakisaraki nile Yoruba, pelu apeere die lara awon ila na. A ko le soro tan lori ila kiko ninu atejade yi, ohun ti a fe se ni lati pe akiyesi wa si asa ila kiko ni le Yoruba gegebi asa ti ko gbodo kase n’le.

Idi Fun Ila Kiko Nile Yoruba
Yoruba maa nkola fun idi meji Pataki. Ikini ni fun idanimo. Laye atijo nigba ogun, ati owo eru, opolopo awon idile lo padanu awon omo, agunbaniro, iyawo ati baba. Awon ti ko ba ku, won a ko won lo sile okeere. Opolopo le pada wale. Nitorina, ki awon to npada wale le mo ilu tabi ile ti won ti kuro ni won se dogbon ila kiko – lati morawon. Idi keji fun ila kiko ni fun ewa. Ti o ba wo oju awon to kola, wa a ri wipe won lewa, ila na si dara loju won, yala okunrin tabi obirin.

Die Lara awon ibiti ila kiko ti wopo nile Yoruba
Die lara awon ibiti ila kiko ti wopo nile Yoruba niwonyi: awon Egba, Ibadan, Ife, Ijesha, Oyo, Ekiti, Ijebu, Ondo, and Owu. Awon ila na pe orisirisi fun apeere, Abaja, Pele, Ture, Gombo, ati Keke.
Attachments
Abaja Alagbele ..Oyo.jpg
Abaja Alagbele - Oyo
Abaja Alagbele ..Oyo.jpg (38.22 KiB) Viewed 1952 times
Ila Pele meta.. Ijesha.jpg
Pele Meta - Ijesha
Ila Pele meta.. Ijesha.jpg (29.69 KiB) Viewed 1952 times
Ila Gombo.. Ibadan and Ogbomosho.jpg
Gombo - Ibadan and Ogbomosho
Ila Gombo.. Ibadan and Ogbomosho.jpg (27.9 KiB) Viewed 1952 times
Abaja Alagbele..Egba and Owu.jpg
Abaja Alagbele - Egba, Ijebu, and Owu
Abaja Alagbele..Egba and Owu.jpg (48.2 KiB) Viewed 1952 times
Ila Ondo.jpg
Ila Ondo
Ila Ondo.jpg (23.12 KiB) Viewed 1952 times

Baba owe
Reactions:
Gender: None specified

Re: YORUBA TRIBAL MARKS

Post by Baba owe » Wed Feb 01, 2017 4:55 pm

Ko ki n se gbogb igba na ni ogun ati ewa je idi ti won fi n ko ila ni ile Yoruba. Aisan ati oro idile na a ma fa ni igba imi. Ohun gan ni o wopo ju ni aiye isiyin.

User avatar
Mayowa
Reactions:
Posts: 538
Joined: Sun Mar 01, 2015 3:23 pm
Gender: Male

Re: Tribal marks in Yoruba land and types

Post by Mayowa » Mon Feb 06, 2017 11:59 am

Alagba Sofunbej, mo ti se afikun akole yin, mo l'ero wipe o ba yin l'ara mu.
E parapo mo wa ki e si pe awon ore yin na wa parapo mo wa. Register with us and invite your friends too.

User avatar
Mayowa
Reactions:
Posts: 538
Joined: Sun Mar 01, 2015 3:23 pm
Gender: Male

Re: Tribal marks in Yoruba land and types

Post by Mayowa » Mon Feb 06, 2017 12:10 pm

Image
Ila Owu / Owu tribal marks

Image

Image
Ila Ọyọ / Ọyọ tribal marks

Image
Ila Ijesha, Ẹfọn, Igbomina, Yagba ati Ondo

Image
Ila Ẹgba, Ijẹbu ati Ifẹ
E parapo mo wa ki e si pe awon ore yin na wa parapo mo wa. Register with us and invite your friends too.

sofunbej
Reactions:
Posts: 16
Joined: Thu Nov 10, 2016 11:29 am
Gender: Male

Re: Tribal marks in Yoruba land and types

Post by sofunbej » Wed Feb 08, 2017 4:59 pm

Olotu,
E se gan an ni. Mo ri awon afikun ti e se.

Sugbon ila ti awon Yagba ti e fikun yen ni o nkomilominu. Emi ro pe awon eya Igala lo ma nko iru ila na ni.
Awon eya Igala yi wa ni ipinle Kogi, ilu won ni Idah. Idah wa nitosi Makurdi ni ipinle Benue, tabi Agenebode legbe Auchi ni ipinle Edo, beeni ko si jinna si Nsukka ni ipinle Anambra.

Abi awon Igala yi na le npe ni Yagba?
E lami loye.

User avatar
Mayowa
Reactions:
Posts: 538
Joined: Sun Mar 01, 2015 3:23 pm
Gender: Male

Re: Tribal marks in Yoruba land and types

Post by Mayowa » Fri Feb 10, 2017 7:29 pm

sofunbej wrote:
Wed Feb 08, 2017 4:59 pm
Olotu,
E se gan an ni. Mo ri awon afikun ti e se.

Sugbon ila ti awon Yagba ti e fikun yen ni o nkomilominu. Emi ro pe awon eya Igala lo ma nko iru ila na ni.
Awon eya Igala yi wa ni ipinle Kogi, ilu won ni Idah. Idah wa nitosi Makurdi ni ipinle Benue, tabi Agenebode legbe Auchi ni ipinle Edo, beeni ko si jinna si Nsukka ni ipinle Anambra.

Abi awon Igala yi na le npe ni Yagba?
E lami loye.
Ẹ má bìnu ẹjọ. O ní àwọn nkan tí kó jẹ́ kí n dáhùn lásìkò. Ìdáhùn mi re:

1. Àwọn àwòrán tí ẹ rí yẹn wá láti inú ìwé kan tí Alagba Samuel Johnson kọ ní ọjọ́ tí ó ti pè. Bí ọdun 18...kinikan lọ kọ bẹ sì ni ọpọlọpo awọn eniyan gba nkan ti o kọ yìí. Kódà tí ẹ bá wá ayélujára, ẹ o ri awọn àwòrán yìí dáadáa tí àwọn ènìyàn kò si fi bẹ́ẹ̀ lòdì si.

2. Mo tún ka nkankan nípa ila. Wọ́n ní ní ibi tí àwọn ènìyàn tí ń rìn ká, wón a má kọ ìlà àwọn ẹ̀yà tí wọ́n bá sunmọ tàbí tí wón kọjá lára rè. Bóyá eléyìí lọ faa tí àwọn Yagba fín fà ìlà Igala.

3. Mo bá ara Igala kan sọ ọ̀rọ̀ lónìí kódà ìlà yìí gangan ló wà ní ẹnu rẹ̀. Mo ní, 'ṣe Igala ni ìlà ẹ̀kẹ́ rẹ ẹ̀?' Ó ní bẹẹni. Mo tún béèrè wípé 'ǹjẹ́ ẹ̀yin àti àwọn Yagba á máa kọ ìlà kan náà bìi? Ó ní rárá o. Ó ní òun kò kì í ń rí ìlà ní ẹ̀kẹ́ àwọn Yagba. Ó ní àwọn l'àwọn ni ilà ná à .

4. Ibi ti mo pa okan sì ni wipe àwọn Igala lo ní ila na àmọ́ boya awọn Yagba ma n kọ ila na a ni igba ti alagba na ń kọ ìwé rẹ.
E parapo mo wa ki e si pe awon ore yin na wa parapo mo wa. Register with us and invite your friends too.

sofunbej
Reactions:
Posts: 16
Joined: Thu Nov 10, 2016 11:29 am
Gender: Male

Re: Tribal marks in Yoruba land and types

Post by sofunbej » Tue Feb 14, 2017 11:03 pm

Olotu,

E se mo ti gbo alaye yin.

Inu mi si dun lati ri ka wipe e pade okan lara awon Igala lakoko ti a nsoro yi, ti o si ko ila na.
Ju gbogbo e lo, o see se ki awon Yagba ati Igala rin pade nibi kan laye atijo ti awon eya mejeeji fi nko iru ila kan na. O damiloju wipe nkan ti a le se iwadi re ni.

Ka dupe lowo Alagba Samuel Johnson (ajeeji) fun ise ti won se niti iwe won lori itan Yoruba.
Ibiti oro ku si bayi, awa na le tesiwaju lori iwadi yi. Mo mo wipe eyi ki i se ise ojo kan tabi ojo meji, sugbon a gbodo gba gegebi ipenija wa lati se awari iru itan bayi to je tiwa n tiwa. O to gee, ibiti alejo ba wa ko itan wa de.

User avatar
Mayowa
Reactions:
Posts: 538
Joined: Sun Mar 01, 2015 3:23 pm
Gender: Male

Re: Tribal marks in Yoruba land and types

Post by Mayowa » Wed Feb 15, 2017 7:49 pm

sofunbej wrote:
Tue Feb 14, 2017 11:03 pm
Olotu,

E se mo ti gbo alaye yin.

Inu mi si dun lati ri ka wipe e pade okan lara awon Igala lakoko ti a nsoro yi, ti o si ko ila na.
Ju gbogbo e lo, o see se ki awon Yagba ati Igala rin pade nibi kan laye atijo ti awon eya mejeeji fi nko iru ila kan na. O damiloju wipe nkan ti a le se iwadi re ni.

Ka dupe lowo Alagba Samuel Johnson (ajeeji) fun ise ti won se niti iwe won lori itan Yoruba.
Ibiti oro ku si bayi, awa na le tesiwaju lori iwadi yi. Mo mo wipe eyi ki i se ise ojo kan tabi ojo meji, sugbon a gbodo gba gegebi ipenija wa lati se awari iru itan bayi to je tiwa n tiwa. O to gee, ibiti alejo ba wa ko itan wa de.
Mo gba tiyín jàre. Àwọn èèyàn tún sọ, wọ́n ní ìtàn Alagba Samuel Johnson l'ori ogun kiriji kò pé tó. A yi ma kọ nipa àwọn nkankan ninu iwe yi ti o ba ya. Lati ibẹ, a ó ri okodoro àwọn ìtàn ti o wa ni inu rẹ.
Àmọ́ ara Ọ̀yọ́ ni Johnson jẹ ó, kò fi gbogbo ara jẹ àlejò.
E parapo mo wa ki e si pe awon ore yin na wa parapo mo wa. Register with us and invite your friends too.

sofunbej
Reactions:
Posts: 16
Joined: Thu Nov 10, 2016 11:29 am
Gender: Male

Re: Tribal marks in Yoruba land and types

Post by sofunbej » Thu Feb 16, 2017 10:31 pm

Olotu,

Mo dupe fun alaye yin.

Latari awon nkan wonyi, mo fe gba yin nimoran ki e kowonjopo gbogbo awon ohun ti o nfarahan bayi to nilo atunko tabi awari lori itan, asa tabi ohun miran to je ti Yoruba to nilo ikobiara si. (Apeere ni itan ila kiko ti Yagba ati Igala yi, bakanna ni itan ogun Kiriji ti e menu ba.)

Lehin na, ki e farabale wa awon ile-ise to ni ife si iru ise akanse na (project) lati gbe Yoruba laruge ti won si le se onigbowo akanse ise yi, paapaajulo atilehin nipa owo tabi ohun elo miran. O seese ka ri lara awon ijoba wa (bi Lagos, Ogun, Osun, Ondo, Ekiti), tabi awon ile-eko giga nibiti won ti nko Yoruba, tabi eka asa ibile ni ile-ise awon asoju ile okeere bi Brazil, USA, Canada tabi awon ajo agbaye bi UNESCO. Lehin eyi, ki e wa awon eniyan mora ti e mo pe won le sise yi pelu yin.

O da mi loju wipe ti ise yi ba seese, a a mu atunse ba awon irohin ti ko kun to nipa Yoruba, a si jeki nkan dara si ju bayi lo.
Mo mo wipe ise nla leyi, sugbon e gbaa yewo.

User avatar
Mayowa
Reactions:
Posts: 538
Joined: Sun Mar 01, 2015 3:23 pm
Gender: Male

Re: Tribal marks in Yoruba land and types

Post by Mayowa » Fri Feb 17, 2017 5:42 pm

A o gbaa yewo, ma a si je ki e mo iha ti mo ko si laipe. E seun mo dupe.
E parapo mo wa ki e si pe awon ore yin na wa parapo mo wa. Register with us and invite your friends too.

Post Reply
  • Similar Topics
    Replies
    Views
    Last post

Who is online

Users browsing this forum: No registered users and 5 guests